About

Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá Nàìjíríà
(Yorùbá Studies Association of Nigeria)

Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá ti Nàìjíríà jẹ́ Ẹgbẹ́ àwọn olùkọ́ ilé-ẹ̀kọ́ gíga àti àwọn bọ̀rọ̀kìnní ọmọ orílẹ̀-èdè yìí tí wọ́n nífẹ̀ẹ́ sí́ ìpolongo ìran Yorùbá àti Lítíréṣọ̀ rè. YSAN jẹ́ Ẹgbẹ́ tí ó ga jùlọ fún ìdàgbàsókè iṣẹ́ ìwádìí nínú ẹ̀kọ́ Yorùbá.

Àwọn akadá àti àwọn olùfẹ́ èdè, lítíréṣọ̀ àti àṣà Yorùbá ni wọ́n dá Ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ ní ọdún 1970. Lára àwọn ènìyàn jàǹkàn-jàǹkàn tí wọ́n dá Ẹgbé yìí sílẹ̀ ni Ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà Adébóyè Babalọlá, Olóògbé Afọlábí Ọlábímtán, Ayọ̀ Bámgbóṣé, Ọládélé Awóbùlúyì,̣ Ayọ̀ Bánjọ, Kújọọ́rẹ̀, Ọlátúndé Ọlátúnjí, Wándé Abímbọ́lá, Akínwùmí Ìṣọ̀lá, Sọpẹ́ Oyèláràn àti Alága Adébáyọ̀ Fálétí.

Ọ̀jọ̀gbọ́n àgbà Adébóyè Babalọlá ni Ààrẹ Ẹgbẹ́ àkọ́kọ́.                   

Èròńgbà YSAN ni láti máa ṣe àgbéga ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gíga. Àwọn àgbààgbà tó dá Ẹgbẹ́ yìí sílẹ̀ pinnu láti fi ìdí ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá múlẹ̀ ní ìpele àṣà, èdè àti lítíréṣọ̀, àti ríi dájú pé ẹ̀kọ́ èdè Yorùbá di gbajúgbajà. Ẹgbẹ́ yìí sapá láti ríi pé òun ṣe àṣeyọrí nínú àwọn èròńgbà rẹ̀.

Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ máa ń péjọ lóòrè-kóòrè fún ìdánilẹ́kọ̀ọ́, sẹminá àti àpérò. Láti ríi dájú pé iṣẹ́ ìwádìí àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ di èyí tí à ń rí kà, Ẹgbẹ́ ṣe ìdásílẹ̀ Jọ́nà tí a pè ní YORÙBÁ nínú èyí tí àwọn átíkù tó pegedé tí ń hànde. Àwọn ọ̀mọ̀wé nínú lítíréṣọ̀ èdè Gẹ̀ẹ́sì, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀-ẹ̀rọ, agbóyọ àti ìmọ̀ ìṣirò náà máa ń gbé iṣẹ ìwádìí wọn tó jẹ mọ́ góńgó-ìlépa àti èròńgbà Ẹgbẹ́ jáde nínú YORÙBÁ. Jọ́nà yìí sì wà ní orí àtẹ títí di òní láti ọdún tí àtẹ̀jáde àkọ́kọ́ ti wáyé.

Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá Nàìjíríà (YSAN) ti ṣe ìwádìí lórí ìmọ̀ ẹ̀dà-èdè ilẹ̀ Áfíríkà, ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ ẹ̀rọ àti ọ̀rọ̀ lámẹ̀ẹ́tọ́ ajẹmọ́ lítíréṣọ̀, ìdásílẹ̀ Ẹgbẹ́ yìí ti ṣe akitiyan fún ìjọba Àpapọ̀ nípa pípèsè Kọ̀ríkúlọ̀mù tuntun fún ìtòlẹ́sẹẹsẹ ètò ẹ̀kọ́ onípele mẹ́rin tí à ń pè ní 6-3-3-4. Gẹ́gẹ́ bí àṣeyọrí akitiyan rẹ̀. Ẹgbẹ́ yìí ti ṣe àgbéjáde ìdì méjì ìwé èdè ìperí Yorùbá lábẹ́ ìgbọ̀wọ́ Nigeria Education Research Development Council (NERDC). Èdè ìperí jẹ́ atúmọ̀ ọ̀rọ̀-ìperí àwọn ọ̀rọ̀ tó ta kókó nínú èdè Gẹ̀ẹ́sì sí Yorùbá. Ìwé yìí ti di ohun èlò kòseémánìí fún kíkọ́ gírámà àti lítíréṣọ̀ Yorùbá ní àwọn ilé-ẹ̀kọ́ gbogbo.

Àwọn ọmọ Ẹgbẹ́ ti lọ́wọ́ nínú kíkọ èdè àmúlò òṣèlú fún àwọn ilé ìgbìmọ̀ aṣòfin ní apá ìwọ̀ oòrùn ilẹ̀ Nàìjíríà. Ní àfikún, Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá èyí tí àjọ UNESCO ṣe onígbọ̀wọ́ rè. Ìwé yìí kò tíì dé orí àtẹ nítorí àìsí owó.

Name 
The Association shall be called Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá Nàìjíríà (The Yoruba Studies Association of Nigeria).
Aims
The Aims of the Association shall be:
(a) To promote the academic development of Yoruba studies.
(b) To initiate, encourage and support scholarly research in Yoruba Studies.
(c) To promote and encourage the development of courses in Yoruba Studies at all levels of education in Nigeria and Overseas.
(d) To establish a learned journal of Yoruba Studies to be published regularly. (The aspiration of the Association is to publish the journal entirely in Yoruba, but it may initially be bilingual).
(e) To undertake such other activities as are consistent with the foregoing aims.

News Update

 
Yoruba: Journal of the YSAN 2013

Yoruba: Journal of the Yoruba Studies Association of Nigeria is currently published by the Yoruba Studies Association of Nigeria (YSAN) twice a year... Read More

Our Publications

Click Here

Have free access to our publications

Member Login

Membership Sign Up