Papers

Ẹgbẹ́ Onímọ̀-Èdè Yorùbá Nàìjíríà
(Yorùbá Studies Association of Nigeria)

Abstracts

Àyẹ̀wò Àfihàn Obìnrin, Ogun Jíjà àti Ọrọ̀-Ajé Nínú Àṣàyàn Ìwé Eré-Onítàn Yorùbá


Author: Olúfadékẹ́mi (Aya) Adágbádá, Ph.D.

Àṣamọ̀


Gẹ́gẹ́ bíi ti í rí nínú àwọn àwùjọ akọlolú káàkiri àgbáyé; ipò ẹnìkejì, ẹni ẹ̀yìn, ẹni àtẹ̀mẹ́rẹ̀; ohun ẹlẹgẹ́ tí kò ní agbára kan dàbí alárà, àmọ́ tí ojúlówó ìwúlò rẹ̀ wà nínú iṣẹ́ ìbí, ọmọ wíwò pẹ̀lú ọkọ àti ẹbí títọ́jú ni a to obìnrin sí ni àárín àwọn Yorùbá. Ojú àmúwáyé yìí a máa hàn nínú àwọn iṣẹ́ àtinúdá bíi ìwé (eré-onítàn) kíkọ, pàápàá  láti ọwọ́ àwọn òǹkọ̀wé-kùnrin. Èyí kò le ṣe aláìríbẹ́ẹ̀ níwọ̀n ìgbà tí ó jẹ́ pé àwòjíìjìí àwùjọ ni lítíréṣọ̀ ń ṣe. Àfojúsùn wa nínú pépà yìí ni láti ṣe àgbéyẹ̀wò ipò tí àwọn òǹkọ̀wé eré-onítàn to àwọn abo sí nínú àwọn àṣàyàn ìwé tí kókó-ìtàn wọn ní í ṣe pẹ̀lú ogun (abẹ́lé) jíjà ní ilẹ̀ Yorùbá. Àwọn ìbéèrè tí a fẹ́ wá ìdáhùn sí ni pé, ṣé ojú ohun ẹlẹgẹ́ àti aláìlágbára tí àwùjọ fi wo abo yìí lè jẹ́ kí wọ́n wúlò nínú ogun jíjà? Ǹjẹ́ àwọn abo gan-an a máa ṣí/fà/ja ogun? Ní àwọn ọ̀nà wo ni obìnrin fi lè jẹ okùnfà ìdíwọ́ tàbí ìrànlọ́wọ́ fún bíborí ogun? Ǹjẹ́ obìnrin lè ṣaájú ogun kí wọ́n sì jà á ní àjàborí? Yàtọ̀ sí ìwọ̀nyí, àwọn àkóbá tàbí àǹfààní wo ni ó wà nínú ètò ọrọ̀-ajé àwùjọ láti ipasẹ̀ àwọn abo lásìkò ogun tàbí dúkùú? Ìwádìí wa fi hàn pé ìrísí tàbí ìṣẹ̀dá tí ń mójú ọkùnrin má-wọn-wọ́n, ète láti gbọn ìwọ̀sí àti ìrẹ́jẹ akọ dànù àti ìwàǹwára àtilà a máa sọ abo di ọ̀dádá ogun. Yàtọ̀ sí èyí, wọn a máa dúró bíi ibi ìsádi, ààbò àti aláfọ̀rọ̀lọ̀ fún àwọn olórí àti jagunjagun lásìkò ogun. Àwọn abo a máa ṣiṣẹ́ amí nínú ogun, èyí tí ó lè la fífí ẹ̀mí ẹni tàbí dúkìá jin ààbò àti ìlọsíwájú ilẹ̀ ìbí ẹni. Bí ó bá di kàráǹgídá, àwọn obìnrin a máa gbé ìhámọ́ra ogun wọ̀, pàápàá bí ìdíwọ́ kan bá dé bá ètò kárà-kátà nínú ìlú wọn tàbí tí olórí ìlú kan bá ń fèrùú ṣèlú, tí gbogbo ipá mìíràn ti pin láti dá irú ìṣèlú bẹ́ẹ̀ dúró. Tíọ́rì Soṣiọ́lọ́jì (Sociology) tí a fi ṣe ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ ìwádìí yìí ni ìṣẹ̀tọ́fábo ní èròǹgbà Ògúndípẹ̀ (2007) àti ti Máàsì (Marx) gẹ́gẹ́ bí Haralambos àti àwọn yòókù (2008) ṣe yànnàná rẹ̀.


Kókó Ọ̀rọ̀: Àwùjọ, Obìnrin, Ogun, Ìfarajìn, Ọrọ̀-ajé

 

 

Ìlò Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀ Ìgbàlódé Fún Ìpolongo Òògùn Ìbílẹ̀ Yorùbá


Author: Àránsí Ayọ̀ọlá Ọládùúnkẹ́, Ph.D.

Àṣamọ̀
Ohun tó jẹ wá lógún nínú iṣẹ́ ìwádìí yìí ni síṣe àfihàn ọ̀nà tí àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ ń gbà láti ṣe ìpolongo ara wọn pẹ̀lú òògùn tí wọ́n ṣe fún àwọn ènìyàn nínú àwùjọ fún ìmúláradá, ìtọ́jú àti ìdènà àrùn. A ṣe àfihàn ìlànà ìpolówó òògùn láyé àtijọ́ àti òde-òní èyí tó fún wa láyè láti jẹ́ kí a mọ ìyàtọ̀ àti ìjọra tó wà nínú méjèèjì. A wo ìlànà tí wọ́n gbà ṣe ìkọ̀ọ̀kan wọn láti baà lè fi hàn pé bí ìlànà ìgbàlódé ṣe dára tó náà ni àbùkù ṣe wà níbẹ̀.
Ọ̀nà tí a gbà ṣe ìwádìí ni pé, a fi ọ̀rọ̀ wá àwọn oníṣègùn ìbílẹ̀ tí a yàn láàyò pẹ̀lú àwọn alárenà ètò ìpàtẹ òògùn ní ilé-iṣẹ́ rédíò àti tẹlifísàn lẹ́nu wò. A ṣe ìwádìí nípa iṣẹ́ òògùn wọn, bátànì tí wọn ń lò láti tajà wọn, ibi tí wọ́n tí ń ṣe òògùn wọn àti ibi tí a ti lè rí wọn rà. Iṣẹ́ yìí jẹ́ kí a mọ̀ pé ìlò ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé ń polongo iṣẹ́ ìṣègùn àwọn Yorùbá fún àwọn tí kì í ṣe ọmọ Yorùbá. Ó tún jẹ́ kí a mọ̀ pé òògùn ìbílẹ̀ Yorùbá tayọ àwùjọ Yorùbá nítorí ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn tí kì í ṣe ọmọ Yorùbá ló ní àǹfààní láti gbọ́ ìpolówó òògùn wọn. Síwájú sí i, ìlò ibánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé tún jẹ́ kí òògùn Yorùbá jẹ́ ìlú mọ̀-ọ́n-ká. Yàtọ̀ sí èyí, ó jẹ́ kí á mọ̀ pé àwọn òògùn ẹ̀yà mìíràn tún ń jẹyọ nínú ọgbọ́n ìṣègùn ẹ̀yà Yorùbá. Ìpolówó òògùn lórí ẹ̀rọ ìbánisọ̀rọ̀ ìgbàlódé jẹ́ kí òògùn ìbílẹ̀ Yorùbá gbòòrò sí i, èyí sì jẹ́ orísun ìdàgbàsókè iṣẹ́ abínibí ìran Yorùbá.

Kókó Ọ̀rọ̀: Ọ̀nà Ìbánisọ̀rọ̀, Òògùn Ìbílẹ̀, Ìpolongo, Yorùbá

 

 

“Ó” Kì í Ṣe Arọ́pò-Orúkọ Yorùbá: Ẹ̀rí Tuntun


Author: Ọládélé Awóbulúyì, Ph.D.

Àṣamọ̀


'Un' ni arọ́pò-orúkọ kúkúrú ẹni kẹta ẹyọ inú èdè Yorùbá. Ìtumọ̀ rẹ̀, ìyẹn 'ẹni kẹ́ta ẹyọ', tí ó máa ń wà ní àyè olùwà níwájú 'ó', ni ó máa ń mú kí gbogbo ìsọ bí 'Ó wà níbẹ̀' ṣe ìròyìn tàbí àlàyé nípa ẹni kẹ́ta ẹyọ nínú èdè Yorùbá àjùmọ̀lò.

 

 

Àyẹ̀wò Ogun Ẹnu Nínú Àṣàyàn Fíìmù Àgbéléwò Yorùbá


Author: Olúyẹ́misí Adébọ̀wálé, Ph.D., Tèmítọ́pẹ́ Olúmúyìwá, Ph.D. and Jùmọ̀kẹ́ Aṣíwájú, Ph.D.

Àṣamọ̀


Oríṣi ogun méjì tí ó lè dojú kọ ẹ̀dá nílé ayé ni ogun rírí àti ogun àìrí. Ọ̀kan lára ogun àìrí tí ó lè ja ènìyàn ni ogun ẹnu. Ogun ẹnu kì í ṣe ogun tí a ń fi nǹkan ìjà olóró bí ìbọn, ọ̀kọ̀, ọfà tàbí àdá jà. Kí wá ni a fi ń jà á?


Báwo ni a sì ṣe ń jà á? Akitiyan àtiwá ìdáhùn sí àwọn ìbéèrè wọ̀nyí wà lára ohun tó gún wa ní kẹ́ṣẹ́ láti ṣe àyẹ̀wò ogun ẹnu nínú àṣàyàn fíìmù àgbéléwò Yorùbá tó lé lógún. A kọ́kọ́ ṣe àmúlò èrò Yorùbá gẹ́gẹ́ bí ó ṣe jẹyọ nínú òwe láti sọ ohun tí ogun ẹnu jẹ́. Bákan náà ni a ṣe àlàyé pé àwọn ohun tí ó lè ṣe okùnfà ogun ẹnu láwùjọ Yorùbá tí a gbé àwọn àṣàyàn fíìmù tí a yẹ̀wò lé ni ìlara, ìrẹ́jẹ, ipò àti yíyẹ àdéhùn. Àwọn nǹkan tí a fi ń ja ogun ẹnu tí iṣẹ́ yìí mẹ́nubà ni èpè, ọfọ̀, orin àti èébú. Oríṣiríṣi ohun tí ó lè fa kí ogun ẹnu ja ẹ̀dá tí ó hànde nínú àṣàyàn fíìmù tí a ṣàyẹ̀wò ni a fi kásẹ̀ àlàyé wa nílẹ̀.

 

 

Ọ̀rọ̀ Àbínúkú Nínú Ewì Alohùn Èdè Yorùbá


Author: Dúró Adélékè, Ph.D.

Àṣamọ̀


Ó hànde pé àwùjọ kan, níbi tí oríṣìí ẹ̀dánìyàn wa, dandan ni kí àjoṣe wà láàárín àwọn ẹlẹ́gbẹ́jẹgbẹ́, ẹlẹ́yàjẹ̀yà, oníranjìran àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Nípasẹ̀ àjọṣepọ̀ tí ó wáyé láti ibi ìbára-ẹni-gbépọ̀ yìí ni ìran tàbí ẹ̀yà kan fi n fi ìmọ̀sílára hàn sí ara wọn. Kálukú wọn ni wọ́n mọ irúfẹ́ ojú tí wọ́n fi ń wo ara wọn àti irúfẹ́ èrò tí wọn ń gbà nípa ara wọn. Nígbà tí àjọṣepọ̀ bá gbọ̀nà òdì, kóówá wọn á wá fi ìhà tí wọn kọ sí ara wọn hàn nípàtó nípa lílo ọ̀rọ̀ tàbí ìpèdè àbínúkú tí wọn ti gbìn sọ́kan sí ara wọn. Àfojúsùn pépà yìi ni láti ṣàgbéyẹ̀wó àwọn ọ̀rọ̀ àti ìpèdè àbínúkú tí ń jẹyọ nínú àwọn ewì alohùn bíi oríkì àti òwe. Eékì ọ̀rọ̀ àbínúkú àti tíọ́rì aáwọ̀ ni a fi ṣe àwòta àti ọ̀pákùtẹ̀lẹ̀ iṣẹ́ yìí. Àkójọ èdè fáyẹ̀wò iṣẹ́ yìí ni a fàyọ nínú oríkì, òwe ati ọ̀rọ̀  ọgbọ́n Yorùbá. Ẹ̀rí fi hàn pé ìpèdè àbínúkú lè ta bá ẹ̀yà tí kì í ṣe ìran Yorùbá, ẹ̀ka èdè láàárin ìran Yorùbá, ẹlẹ́sìn, abirùn àti bẹ́ẹ̀ bẹ́ẹ̀ lọ. Pépà yìí fi hàn pé nípasẹ̀ àbúdá àdámọ́ bi ìrísí, ètò ọrọ̀-ajé àti bẹ́ẹ̀ lọ ni ọ̀rọ̀ àti ìpèdè àbínúkú ṣe gbilẹ̀ bi ọ̀wàrà òjò. 

 

 

Aáwọ̀ Láàrin Ẹlẹ́yàmẹ̀yà Bí Ó ti Hànde Nínú Lítíréṣọ̀ Yorùbá


Author: Àrìnpé Adéjùmọ̀, Ph.D.

Àṣamọ̀


Àkíyèsí àwọn onímọ̀ ti fi hàn pé ọ̀kan pàtàkì lára àrùn jẹjẹrẹ tó ń bá orílẹ̀-èdè Nàíjíríà fínra ni ogun ẹléyàmẹyà jẹ́. Àtubọ̀tán èyí ni ó fa kíkùnà tí àwọn aṣáájú olóṣèlú láwùjọ Náìjíríà kùnà láti ṣe ìjọba tí yóò máyé rọrùn fún tẹrú-tọmọ. Ìdí nìyí tí àwọn onímọ̀ lónírúurú fi ń gbìyànjú àtiwá ọ̀nà àbáyọ kúrò nínú ẹlẹ́yàmẹ̀yà  tó ń ja ra-in lórílẹ̀-èdè yìí. Àwọn oníṣẹ ọnà – aláwòmọ́ lítíréṣọ̀ náà kò gbẹ́yìn nínú ọ̀rọ̀ wíwá ọ̀nà àbáyọ sí ọ̀rọ̀ ogun ẹlẹ́yàmẹyà. Nínú àpilẹ̀kọ yìí, a lo tíọ́rì ìmọ̀ ajẹmọ́tàn-tuntun láti ṣàyẹ̀wò bí àwọn oníṣẹ́ ọnà lítírésọ̀ kan ṣe ṣàwòtàn ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà ni orílẹ̀-èdè Náìjíríà. Àṣàyàn à-mọ́-mọ̀ ṣe ni a mú lò láti yan àwọn ìwé lítíréṣọ̀ tí a tú palẹ̀. Àfàyọ tí a rí ni pé ogun ẹlẹ́yàmẹ̀yà tí takàn ní orílẹ̀-èdè Nàíjíríà; ìdí ni pé máyàmí ni ìṣèlú àti ọ̀rọ̀ ẹlẹ́yàmẹ̀yà jẹ́. Ọ̀nà àbáyọ tí a rí fàyọ ni pé ẹ̀yà kan kò gbọdọ̀ rí ara rẹ̀ bí ẹ̀yà tó ga jù tàbí èyí tó dára jú èkejì lọ. Iṣẹ́ yìí fihàn  pé ìṣọ̀kan ló gbọdọ̀ jẹ́ ọ̀rọ̀ ìdákọ̀rọ fún gbogbo ẹ̀yà tó wà lórílẹ-èdè yìí. Bákan náà, àṣà alájọgbé, ìwà ọmọlúàbí àti ohun àmúyẹ òun àkàsí àwùjọ Áfíríkà gbọdọ̀ di ohun tí tolórí-tẹlẹ́mù àti àwọn aṣèjọba mú ní ọ̀kúnkúndùn. Ní ìkádìí, iṣẹ́ yìí dá a lábàá pé ìwà ọmọlúàbí t'ó ń gbé àwùjọ Áfíríkà ró ní ìgbà ìwàsẹ̀ gbọdọ̀ di kíkọ ní ilé ẹ̀kọ́ àti ní ibi iṣẹ́ ìjọba kí ìdàgbàsókè abánikalẹ̀ lè tó orílẹ̀-èdè Náíjíríà lọ́wọ́.

 

 

Qualified Bare Nouns in Scopal Contexts in Yorùbá


Author: Ọládiípọ̀ Ajíbóyè, Ph.D.

Abstract


Contrary to the impression conveyed in the literature that the expression [count noun + náà] gives the noun a definite interpretation, we discover that such nominal expression remains ambiguous in most contexts between two readings, which for ease of reference we can label as the identity reading and the additive reading, and the latter in turn can be either indefinite or definite: ajá náà = "the very dog", "a dog also", "the dog under discussion also".


For this reason, we regard náà as a salience qualifier, distinct from a determiner in a manner to be made more precise. Notice that the ambiguity of "náà" is independent of the ambiguity of the bare noun; hence the combination allows no less than three possible readings. (We suggest provisionally that the fourth logical possibility, "a very dog" is presumably excluded on independent grounds of illformedness, as the notion of "indefinite identity" seems to be semantically incoherent.) Here we add a third observation which is apparently novel although we would be encouraged if it has been made before now: the additive reading disappears in a particular scopal context, namely when the bare noun qualified by "náà" is extracted from the scopal domain of a modal (e.g., lè 'possibility', gbọ́dọ̀ 'necessity', kò 'negation, perhaps among others) in a focus cleft or pseudocleft. Just in this context, so far as we are able to determine, the sense of "also" (additivity) is obligatorily replaced by the sense of "only" (uniqueness). Note that the basic ambiguity of the bare noun between definite and indefinite interpretations remains in this context, and that the identity interpretation of "náà" is unaffected by the extraction: ajá náà ni [... MOD...] ] = "the very dog", "only a dog, only the dog under discussion. We propose that the modality scope effect holds, to our knowledge, across diverse semantic types of modals including possibility, necessity and negation. This suggests that the effect is computed in the syntax, where scope holds uniformly for the same configuration, rather than in the semantics/pragmatics where configuration is not recoverable.


 


Keywords: Qualified Bare Nouns, Scopal Contexts, Yorùbá

 

 

Presupposition Triggers and their Semantics in Yorùbá


Author: Fọlọrunṣọ Ilọri, Ph.D.

Abstract


Very few studies exist on the semantic structure of Yorùbá language. This dearth leaves an appreciable gap yearning to be filled in the overall understanding of the linguistic structure of the language as lack of crucial information on the semantic structure of various constructions, especially at the level of syntax, continues to hinder in-depth understanding and formal description. This paper investigates Yorùbá presupposition triggers: first by identifying them in their various constructions as signposts of the phenomenon; and second by providing a formal semantic description of the kinds of entailment they propel. Findings do not only attest to the universality claim about presupposition in natural language semantics but also show that triggers of the phenomenon exist across nominal, verbal, and adverbial projections in the language.


 


Keywords: Presupposition, Triggers, Entailment, Semantics, Yorùbá language

 

 

An Ethnographic Analysis of Christo-Pilate’s Discourse


Author: Jacob Olúdáre Olúwádọrọ̀, Ph.D.

Abstract


Much scholarly attention has been devoted to the analysis of the Bible as a literary masterpiece. So also is Dell Hymes’ Ethnography of Communication, which started out as ‘Ethnography of Speaking’. However, to the best of the researcher’s knowledge, no sociolinguistic attention has been devoted to the ‘judgement scene’ of ‘Jesus trial’ prior to his crucifixion. This paper, therefore, examines the interaction of Pilate with Jesus, as well as, his accusers (the Jews), with a view to ascertaining its sociolinguistic relevance. Data was extracted from the King James Version of the Holy Bible, especially, John chapters 18 and 19. Though, the Synoptic Gospels of Matthew, Mark, Luke and John reported the case, however, John’s accounts were more detailed than the others. The theoretical framework applied was Hymes’ Ethnography of Communication. Our data is made up of 22 texts extracted from Jesus’ trial scene. Twelve (12) of the statements were uttered by Pilate, who represents the judge. Nine out of the twelve were direct questions, directed at Jesus (the accused) and the Jews (his accusers). The remaining four are declarative sentences. Four were uttered by Jesus Christ, three of which are affirmatives of different forms and one question, directed at Pilate. The remaining six utterances were made by the Jews, comprising the chief priests, the officers and others. The Christo-Pilate’s interrogation constitutes an interesting ethnographic exploration.


Key words:   Ethnography of Communication, Christo-Pilate’s Discourse, Sociolinguistics, Trial, the Jews

 

 

Previous | Next

Our Publications

Click Here

Have free access to our publications

Member Login

Membership Sign Up